Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rome

41 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.

  2. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìnrere Ọlọ́run sí i yín.

  3. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.

  4. Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn.

  5. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

  6. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn.

  7. Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá,

  8. wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà.

  9. Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́.

  10. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.

  11. Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà.

  12. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.

  13. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe.

  14. Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́.

  15. Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí,

  16. aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú.

  17. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

  18. Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń péjọpọ̀ ní ilé wọn. Ẹ kí Epenetu ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di ti Kristi ní orílẹ̀-èdè Asia.

  19. Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ṣe làálàá púpọ̀ lórí wa.

  20. Ẹ kí Androniku àti Junia, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrín àwọn aposteli, wọ́n sì ti wà nínú Kristi ṣáájú mi.

  21. Ẹ kí Ampliatu, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.

  22. Ẹ kí Urbani, alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Kristi àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Staki.

  23. Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu.

  24. Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi. Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa.

  25. Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa. Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.