Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rome

41 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú.

  2. Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  3. Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  4. Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín. Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.

  5. Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn.

  6. Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere.

  7. Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi.

  8. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

  9. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.

  10. Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi.

  11. Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìyìnrere.

  12. Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí. Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀,

  13. Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.

  14. Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.

  15. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi.

  16. Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin.