Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Publicans

32 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́?

  2. Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?

  3. Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  4. Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”

  5. Filipi àti Bartolomeu; Tomasi àti Matiu agbowó òde; Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

  6. Ọmọ Ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”

  7. Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.

  8. “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?” Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.” Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín.

  9. Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

  10. Bí ó ti ń rin etí Òkun lọ sókè, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” Lefi dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.

  11. Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e.

  12. Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”

  13. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”

  14. Lẹ́hìn èyí, Jesu jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Lefi, ó jókòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,”

  15. Lefi sì ṣe àsè ńlá kan fún Jesu ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.

  16. (Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi.

  17. Gbogbo àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  18. Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn,

  19. pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.

  20. Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

  21. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

  22. “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’

  23. “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”

  24. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀.

  25. Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú.