Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pilgrims and Strangers

53 ẹsẹ · 35 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.

  2. “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

  3. Jakọbu sì dá Farao lóhùn, “Ọdún ìrìnàjò ayé mi jẹ́ àádóje, ọjọ́ mi kò pọ̀, ó sì kún fún wàhálà, síbẹ̀ kò ì tí ì tó ti àwọn baba mi.”

  4. Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì.

  5. Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ́ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.

  6. Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

  7. Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

  8. Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí.

  9. “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi. Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ, àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

  10. Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde, jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí; jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ, sí ibi tí ìwọ ń gbé.

  11. Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

  12. Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ wọn sọ ọ́ di kànga àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.

  13. Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

  14. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé, má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.

  15. Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.

  16. Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!

  17. Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.

  18. Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.

  19. Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.

  20. “Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ.

  21. “Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?

  22. Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

  23. Jesu sì wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

  24. Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.

  25. “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.