Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pharaoh: 8. Pharaoh Nechoh, his invasion of Assyria and Josiah's death

17 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa 8. Pharaoh Nechoh, his invasion of Assyria and Josiah's death

  1. Nígbà tí Josiah jẹ́ ọba, Farao Neko ọba Ejibiti gòkè lọ sí odò Eufurate láti lọ ran ọba Asiria lọ́wọ́. Ọba Josiah jáde lọ láti lọ bá a pàdé lójú ogun ṣùgbọ́n Neko dojúkọ ọ́, ó sì pa á ní Megido.

  2. Ìránṣẹ́ Josiah gbé ara rẹ̀ wá nínú kẹ̀kẹ́ láti Megido sí Jerusalẹmu ó sì sin ín sínú isà òkú rẹ̀. Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah. Ó fi àmì òróró yàn án, ó sì ṣe é ní ọba ní ipò baba a rẹ̀.

  3. Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Hamutali ọmọbìnrin Jeremiah; ó wá láti Libina.

  4. Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.

  5. Farao Neko sì fi sí inú ìdè ní Ribla ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má ba à lè jẹ ọba ní Jerusalẹmu. Ó sì tan Juda jẹ fun iye ìwọ̀n ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì wúrà kan.

  6. Farao Neko ṣe Eliakimu ọmọ Josiah ní ọba ní ipò baba rẹ̀ Josiah. Ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu. Ṣùgbọ́n ó mú Jehoahasi, ó sì gbé e lọ sí Ejibiti, níbẹ̀ ni ó sì kú.

  7. Jehoiakimu sì san fún Farao Neko fàdákà àti wúrà tí ó béèrè. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó bu owó òde fún ilẹ̀ náà láti san, ó fi agbára gba fàdákà àti wúrà láti ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú iye tí a pín.

  8. Ọba Ejibiti kò sì tún jáde ní ìlú rẹ̀ mọ́, nítorí ọba Babeli ti gba gbogbo agbègbè rẹ̀ láti odò Ejibiti lọ sí odò Eufurate.

  9. Lẹ́yìn gbogbo èyí nígbà tí Josiah ti tún ilẹ̀ náà ṣetán, Neko ọba Ejibiti gòkè lọ láti bá Karkemiṣi jà lórí odo Eufurate, Josiah sì jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ibi ìjà.

  10. Ṣùgbọ́n Neko rán ìránṣẹ́ sí i wí pé, “Ìjà wo ni ó ń bẹ láàrín èmi àti ìwọ, ọba Juda? Kì í ṣe ìwọ ni èmi tọ̀ wá ní àkókò yìí, ṣùgbọ́n, ilé pẹ̀lú èyí ti mo bá níjà. Ọlọ́run ti sọ fún mi láti yára àti láti dúró nípa ṣíṣe ìdènà Ọlọ́run, ẹni tí ó wà pẹ̀lú mi, kí òun má bá a pa ọ́ run.”

  11. Josiah, kò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ara rẹ̀ dà kí ó le bá a jà, kó sì fi etí sí ọ̀rọ̀ Neko láti ẹnu Ọlọ́run wá, ó sì wá jagun ní àfonífojì Megido.

  12. Tafàtafà sì ta ọfà sí ọba Josiah, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè pé, “Ẹ gbé mi kúrò, èmi ti gba ọgbẹ́ gidigidi.”

  13. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbé e jáde kúrò nínú kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbé e sínú kẹ̀kẹ́ mìíràn, wọ́n sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, níbi tí ó ti kú, wọ́n sì sin ín sínú ọ̀kan nínú àwọn ibojì àwọn baba rẹ̀, gbogbo Juda àti gbogbo Jerusalẹmu sì ṣọ̀fọ̀ Josiah.

  14. Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti tálẹ́ǹtì wúrà kan.

  15. Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti.

  16. Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

  17. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.