Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Passover

161 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, a múra ìsìn náà sílẹ̀, àwọn àlùfáà sì dúró ní ipò wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nípa iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ.

  2. Ní ti àjọ ìrékọjá a sì pa ẹran, àwọn àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà tí wọ́n gbé sí ọwọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ Lefi sì bọ ẹranko.

  3. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Lefi pa ọ̀dọ́-àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.

  4. Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun àní nígbà tí a yàn; ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.

  5. Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já. Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

  6. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.

  7. Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà.

  8. Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  9. Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.

  10. “Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”

  11. Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”

  12. Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Ó wí pé, “Kí gbogbo yín mu nínú rẹ̀.

  13. Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  14. Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni.

  15. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.

  16. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”

  17. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?”

  18. Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  19. Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’

  20. Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.”

  21. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.

  22. Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀.

  23. Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”

  24. Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”

  25. Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni.