Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa National Sins: Cause the withdrawal of privileges
Àwọn ẹsẹ nípa Cause the withdrawal of privileges
Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.
Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro.
Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”