Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa National Sins: Kingdom of Israel

7 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Kingdom of Israel

  1. wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Israẹli tí ó ti paláṣẹ.

  2. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìṣọ́ sí ìlú tí a dáàbò bò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.

  3. Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ̀ sókè àti ère òrìṣà Aṣerah lórí gbogbo igi tútù.

  4. Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n sun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búburú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè.

  5. Wọ́n sìn òrìṣà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”

  6. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà. “Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́, Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà,

  7. àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn olè jíjà àti panṣágà. Wọ́n rú gbogbo òfin, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.