Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa National Sins: Denunciations against

7 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Denunciations against

  1. Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.

  2. “Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;

  3. Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

  4. “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.

  5. Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

  6. Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan, kí ó lè yọ́ òjé, ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán; a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.

  7. A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀, nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”