Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa National Sins: Aggravated by privileges

14 ẹsẹ · 34 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Aggravated by privileges

  1. Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan?

  2. Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

  3. Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì ro ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

  4. Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

  5. Mo sì fún wọn ni òfin mi, mo sì fi àwọn òfin mi hàn wọ́n; nítorí pé ẹni tó bá ṣe wọ́n yóò yè nípa wọn.

  6. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí àmì láàrín àwọn àti èmi, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa tó sọ wọn di mímọ́.

  7. “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.

  8. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé,

  9. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:

  10. “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

  11. Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Korasini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

  12. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín.

  13. Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní.

  14. Lóòótọ́ yóò sàn fún ilẹ̀ Sodomu ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìwọ lọ.”