Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa National Sins: Babylon
Àwọn ẹsẹ nípa Babylon
“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀, àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.