Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Martyrdom

58 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀, ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”

  2. Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó. Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.

  3. “Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”

  4. Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé: “Báyìí ní a ó fi agbára ńlá bí i Babeli ìlú ńlá ni wó, a kì yóò sì rí i mọ́ láé.

  5. Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin, àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè, ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara; àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé. Àti ìró ọlọ ní a kì yóò sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;

  6. Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé; a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé: nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé; nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ.

  7. Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”

  8. Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n, mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.