Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa King

74 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

  2. Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

  3. Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

  4. Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì,

  5. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì, kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,

  6. kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí, kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.

  7. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

  8. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.

  9. Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

  10. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é.

  11. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú.

  12. Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Heberu lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Juda arákùnrin rẹ̀ sìn.

  13. Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbèkùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

  14. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n.

  15. “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

  16. Kí ẹ̀yin kì ó lo òsùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́.

  17. Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òsùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì.

  18. Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ mina kan.

  19. “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan.

  20. Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan).

  21. Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  22. Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli.

  23. Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.

  24. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.

  25. Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.