- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idolatry
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ.
Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”
Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.
Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí ìwọ kí ó rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.”
Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n yà sára ògiri.
Níwájú wọn ni àádọ́rin ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.
Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”
Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Tamusi.
Ó sọ fún mi pé, “Ṣé ìwọ rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”
Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili Olúwa, láàrín ìloro àti pẹpẹ, ni ìwọ̀n ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wà, tí wọ́n kẹ́yìn sí tẹmpili Olúwa tí wọn sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn.
Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn.
Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”
Mo gbọ́ ti ó kígbe ní ohùn rara pé, “Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ itòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́.”
Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà jáde láti ẹnu-ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun gbòò wa láàrín wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.
Ògo Ọlọ́run Israẹli sì gòkè kúrò lórí kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ibi ìloro tẹmpili. Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun náà tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ó sì sọ fún un pé, “La àárín ìlú Jerusalẹmu já, kí ìwọ sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sọkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrín rẹ̀.”
Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sí àárín ìlú láti pa láì dá sí àti láì ṣàánú rárá.
Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kéékèèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn tó ní àmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà tó wà níwájú tẹmpili.
Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹmpili náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrín ìlú.
Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn, mo dójú mi bolẹ̀, mo kígbe pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli nípa dída ìbínú gbígbóná rẹ sórí Jerusalẹmu?”
Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli àti Juda pọ gidigidi; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti àìṣòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’
Nítorí náà, èmi kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú, èmi kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n Èmi yóò dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn.”
Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ó ní ìwo tàdáwà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ròyìn pé, “Mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti pàṣẹ fún mi.”