Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Idolatry

447 ẹsẹ · 205 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi.

  2. Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.

  3. “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.

  4. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.

  5. Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

  6. “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ.

  7. Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́.

  8. Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti.

  9. Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

  10. Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé,

  11. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”

  12. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé,

  13. “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn òkè Israẹli; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn

  14. wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run.

  15. Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.

  16. Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.

  17. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.

  18. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrín yín, ẹ ó sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  19. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi yóò dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè.

  20. Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn.

  21. Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé èmi yóò mú ìdààmú bá wọn.

  22. “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” Ilé Israẹli yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.

  23. Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.

  24. Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrín òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù, níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí olóòórùn dídùn rú ẹbọ sí gbogbo òrìṣà wọn.

  25. Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”