Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Heave-Offering

29 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose sì sọ fún Aaroni, Eleasari àti Itamari àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù pé, “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó ṣẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láìní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

  2. Ẹ jẹ́ ní ibi mímọ́, nítorí pé òun ni ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe pa á láṣẹ.

  3. Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ le jẹ igẹ̀ ẹran tí a fì níwájú Olúwa àti itan tí wọ́n gbé síwájú Olúwa, kí ẹ jẹ wọ́n ní ibi tí a kà sí mímọ́, èyí ni a ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín yín nínú ẹbọ àlàáfíà àwọn ara Israẹli.

  4. Itan tí wọ́n mú wá àti igẹ̀ ẹran tí ẹ fì ni ẹ gbọdọ̀ mú wá pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ tí a finá sun láti le è fì wọ́n níwájú Olúwa bí ẹbọ fífì. Èyí yóò sì jẹ́ ìpín tìrẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ nígbà gbogbo bí Olúwa ṣe pàṣẹ.”

  5. Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.

  6. Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín.

  7. Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa.

  8. “Ìwọ àti Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbèkùn.

  9. Pín ohun ìní àti ìkógun náà láàrín àwọn ọmọ-ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrín gbogbo ìjọ.

  10. Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà, ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran.

  11. Gba ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín tiwọn, kí o sì fún Eleasari àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa.

  12. Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”

  13. Nígbà náà Mose àti Eleasari àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ-ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675,000) àgùntàn.

  15. Ẹgbàá méjìléláàádọ́rin (72,000) màlúù

  16. ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

  17. pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún (32,000), ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.

  18. Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́: ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn.

  19. Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;

  20. ẹgbọrọ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún (36,000), tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàádọ́rin (72);

  21. kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500), tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61).

  22. Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n (32).

  23. Mose fi ìdá náà fún Eleasari, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

  24. Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, tí Mose yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.

  25. Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,