Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Despondency

79 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

  2. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

  3. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.

  4. Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

  5. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

  6. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”

  7. Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.

  8. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

  9. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.

  10. Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.

  11. Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.

  12. Nígbà náà ni mo wí pé, ‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’

  13. Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.

  14. Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.

  15. Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.

  16. Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.

  17. Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́; ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan. Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.

  18. Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.

  19. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

  20. “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

  21. “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.

  22. Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’

  23. Nígbà náà ni “ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Yí lù wá!” Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’

  24. A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

  25. Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;