Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Decision

41 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí.

  2. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ”

  3. Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.

  4. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.

  5. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.

  6. Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.

  7. Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

  8. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

  9. Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”

  10. Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

  11. Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”

  12. Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”

  13. Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi.

  14. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.

  15. Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára,

  16. tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

  17. Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.

  18. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

  19. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.

  20. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.

  21. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu,

  22. kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  23. Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu.

  24. Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

  25. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.