Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Decision: Exhortation to

12 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Exhortation to

  1. Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

  2. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”

  3. Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.”

  4. Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn, ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.”

  5. Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”

  6. Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”

  7. Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.

  8. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

  9. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.

  10. Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.

  11. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu,

  12. kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.