Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Backsliders

196 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí, ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́, ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù.

  2. Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ; o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

  3. Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n, nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.

  4. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí; nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.

  5. Wọ́n fi mí jowú nípa ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run, wọ́n sì fi ohun asán an wọn mú mi bínú. Èmi yóò mú wọn kún fún ìlara láti ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ènìyàn; èmi yóò sì mú wọn bínú láti ọ̀dọ̀ aṣiwèrè orílẹ̀-èdè.

  6. Nítorí pé iná kan ràn nínú ìbínú mi, yóò sì jó dé ipò ikú ní ìsàlẹ̀. Yóò sì run ayé àti ìkórè e rẹ̀ yóò sì tiná bọ ìpìlẹ̀ àwọn òkè ńlá.

  7. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

  8. Èmi yóò mú wọn gbẹ, ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n. Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

  9. Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù, ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá. Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.

  10. Mo ní èmi yóò tú wọn ká èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn,

  11. nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá, kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni; kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”

  12. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.

  13. Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!

  14. Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000), tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

  15. Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.”

  16. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”

  17. Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.” Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.”

  18. Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”

  19. Àwọn ènìyàn náà sì wí fún Joṣua pé, “Olúwa Ọlọ́run nìkan ni àwa yóò máa sìn, òun nìkan ni àwa yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí.”

  20. Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu.

  21. Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ Olúwa.

  22. “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.”

  23. “Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

  24. nígbà náà ni èmi yóò ké Israẹli kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Israẹli yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè.

  25. Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí Olúwa fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’