Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Backsliders

196 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. àti sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti agbede-méjì ẹsẹ̀ rẹ̀ jáde, àti sí àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóò bí. Nítorí òun ó jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí àìní ohunkóhun nínú ìdótì àti ìhámọ́ náà, tí àwọn ọ̀tá yóò fi há ọ mọ́ ní ibodè rẹ.

  2. Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bu ọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,

  3. Olúwa yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́.

  4. Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ.

  5. Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú ìwé òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run.

  6. Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  7. Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

  8. Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.

  9. Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà.

  10. Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ.

  11. Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.

  12. Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.

  13. Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín.

  14. Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà ní àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú àjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà

  15. Olúwa kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjì í; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, Olúwa yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.

  16. Olúwa yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí.

  17. Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àjèjì tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn ààrùn pẹ̀lú tí Olúwa mú bá ọ.

  18. Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Seboimu, tí Olúwa bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀.

  19. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò béèrè pé, “Kí ló dé tí Olúwa fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí? Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí?”

  20. Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ Olúwa Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Ejibiti.

  21. Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn.

  22. Nígbà náà ni ìbínú Olúwa ru sí ilẹ̀ wọn, dé bi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀.

  23. Ní ìbínú àti ní ìkáàánú, àti ní ìrunú ńlá, Olúwa sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.”

  24. Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá; ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán. O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ.

  25. Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú, ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú.