- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Backsliders
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.
“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi.
Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.
Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, nípa kíkùnà láti pa àṣẹ rẹ̀, àwọn òfin rẹ̀, àti àwọn ìlànà rẹ̀ tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀,
nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i,
nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.
Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ.
Ègún ni fún ọ ní ìlú, ègún ni fún ọ ní oko.
Ègún ni fún agbọ̀n rẹ àti ọpọ́n ìpo-fúláwà rẹ.
Ègún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, ìbísí màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
Ègún ni fún ọ nígbà tí o bá wọlé ègún sì ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
Olúwa yóò rán ègún sórí rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀.
Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú ààrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìjóni ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun.
Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.
Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eruku àti ẹ̀tù; láti ọ̀run ni yóò ti máa sọ̀kalẹ̀ sí ọ, títí tí ìwọ yóò fi run.
Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé.
Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.
Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Ejibiti àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.
Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.
Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ tálẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.
Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ́ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èso rẹ.
Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ nǹkan kan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀tá rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.