Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Answers To Prayer

195 ẹsẹ · 85 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn; ìwọ sì di ìgbàlà mi.

  2. Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn, ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

  3. Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.

  4. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.

  5. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

  6. níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

  7. “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

  8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.

  9. Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.

  10. Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

  11. Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.

  12. Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

  13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

  14. “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

  15. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé, Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,

  16. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

  17. Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

  18. Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn; nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.

  19. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn.

  20. Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé.

  21. Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’

  22. “Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.

  23. Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

  24. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

  25. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.