Skip to content

Lehi

3 verses

31.7500, 34.9700 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Lehi

  1. Àwọn ará Filistini sì dìde ogun sí Juda, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbègbè Lehi.

  2. Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

  3. Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìsun omi tí ó wà ní Lehi, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Samsoni mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìsun omi náà ni. Ẹni Hakkore (orísun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Lehi di òní.