Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ammonites

135 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

  2. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

  3. “ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.

  4. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’

  5. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.

  6. Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

  7. Nípa Ammoni. Báyìí ni Olúwa wí, “Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin? Israẹli kò ha ní àrólé bí? Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?

  8. Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí; “nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba tí Ammoni; yóò sì di òkìtì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Israẹli yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni Olúwa wí.

  9. “Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún! Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba! Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà, nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

  10. Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ, ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso? Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘Ta ni yóò kò mí lójú?’

  11. Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  12. “Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.

  13. “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!

  14. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.

  15. “ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.

  16. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà.

  17. Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà, a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín, a kì yóò rántí yín mọ́; nítorí Èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”

  18. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  19. “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ammoni kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn.

  20. Sì wí fún àwọn ará Ammoni pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé. Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,

  21. kíyèsi i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ, wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.

  22. Èmi yóò sì sọ Rabba di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasẹ àti àwọn ọmọ Ammoni di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  23. Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Israẹli

  24. nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

  25. “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,”