Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aaron

145 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ahitubu baba Sadoku. Sadoku baba Ṣallumu,

  2. Ṣallumu baba Hilkiah, Hilkiah baba Asariah,

  3. Asariah baba Seraiah, pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki.

  4. A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

  5. Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni: Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,

  6. Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,

  7. Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,

  8. Sadoku ọmọ rẹ̀ àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.

  9. Àwọn ọmọ Amramu. Aaroni àti Mose. A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé.

  10. Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

  11. Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

  12. Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”

  13. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

  14. Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

  15. Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, àti Aaroni tí ó ti yàn.

  16. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí Olúwa.

  17. Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.

  18. Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’

  19. Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.

  20. tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí ẹ̀rí tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní manna gbé wà, àti ọ̀pá Aaroni tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;