Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aaron: Commissioned as a deliverer of Israel

8 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Commissioned as a deliverer of Israel

  1. Olúwa bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.

  2. Aaroni àti Mose yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.”

  3. Àwọn ni ó bá Farao ọba Ejibiti sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni Ejibiti, àní Mose àti Aaroni yìí kan náà ni.

  4. “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

  5. “Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.

  6. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

  7. Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, àti Aaroni tí ó ti yàn.

  8. Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.