Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aaron: Children of
Àwọn ẹsẹ nípa Children of
Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Putieli ní ìyàwó, ó sì bí Finehasi fún un. Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Lefi ni ìdílé ìdílé.
Àwọn ọmọ Amramu: Aaroni, Mose àti Miriamu. Àwọn ọmọkùnrin Aaroni: Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.