Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aaron

145 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”

  2. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”

  3. Aaroni ṣe bí Mose ti wí, ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrín wọn, ṣùgbọ́n Aaroni fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn.

  4. Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró.

  5. Olúwa sì sọ fún Mose pé,

  6. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.

  7. Lórí ọ̀pá Lefi kọ orúkọ Aaroni, nítorí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan.

  8. Kó wọn sí àgọ́ ìpàdé níwájú ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín.

  9. Ọ̀pá tí ó bá yí jẹ́ ti ẹni tí èmi bá yàn yóò rúwé, èmi yóò sì dá kíkùn gbogbo ìgbà àwọn ọmọ Israẹli sí yín dúró.”

  10. Nígbà náà Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, àwọn olórí wọn sì fún un ní ọ̀pá méjìlá, ọ̀pá kan fún olórí kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà ìran wọn, ọ̀pá Aaroni sì wà lára àwọn ọ̀pá náà.

  11. Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.

  12. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan, ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi.

  13. Nígbà náà ni Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá jáde láti iwájú Olúwa wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wò wọ́n, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì mú ọ̀pá tirẹ̀.

  14. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”

  15. Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.

  16. Àwọn ọmọ Israẹli sọ fún Mose pé, “Àwa yóò kú! A ti sọnù, gbogbo wa ti sọnù!

  17. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ tabanaku Olúwa yóò kú. Ṣé gbogbo wa ni yóò kú?”

  18. Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ àti ìdílé baba rẹ ni yóò ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá fún ilé tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, àti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóò máa ru ẹ̀ṣẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà yín.

  19. Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  20. Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni,

  21. Òun àti Aaroni pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mose sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

  22. Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

  23. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

  24. Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  25. “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba.