Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Aaron

145 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”

  2. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.

  3. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

  4. Mose àti Aaroni sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.

  5. Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”

  6. Mose tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ́ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkùn ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”

  7. Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”

  8. Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọsánmọ̀.

  9. Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, Aaroni gbé manna sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́.

  10. Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ.

  11. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”

  12. Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.

  13. Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ.

  14. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀.

  15. Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.”

  16. “Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

  17. Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Aaroni, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

  18. Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Aaroni arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ ó ta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà.

  19. “Ìwọ yóò dá ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ fún wọn, kí wọn lè máa fi bo ìhòhò wọn, kí ó dé ìbàdí dé itan.

  20. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́ṣẹ̀, wọn a sì kú. “Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Aaroni àti fún irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

  21. ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé. “Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́.

  22. Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

  23. Mose sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Eleasari àti Itamari pé, “ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ nípa ṣíṣe aláìtọ́jú irun yín tàbí kí ẹ ṣí orí yín sílẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ ya aṣọ, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, Olúwa yóò sì bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí yín, àti gbogbo ilé Israẹli le è ṣọ̀fọ̀ lórí àwọn tí Olúwa fi iná parun.

  24. Olúwa sì sọ fún Aaroni pé.

  25. Aaroni sì dá Mose lóhùn pé, “Lónìí tí wọ́n rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun wọn níwájú Olúwa ni irú èyí tún ṣẹlẹ̀ sí mi. Ǹjẹ́ inú Olúwa yóò wá dùn bí mo bá jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí?”