- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Samuẹli 3:17nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Abneri sì bá àwọn àgbàgbà Israẹli sọ̀rọ̀ pé, “Ẹ̀yin ti ń ṣe àfẹ́rí Dafidi ní ìgbà àtijọ́, láti jẹ ọba lórí yín.
- 2 Samuẹli 3:18nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ ẹ ṣe, nítorí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi pé, ‘Láti ọwọ́ Dafidi ìránṣẹ́ mi lé mi ó gba Israẹli ènìyàn mi là kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn.’ ”
- 2 Samuẹli 3:19nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Abneri sì sọ̀rọ̀ létí Benjamini: Abneri sì lọ sọ létí Dafidi ní Hebroni, gbogbo èyí tí ó dára lójú Israẹli, àti lójú gbogbo ilé Benjamini.
- 2 Samuẹli 3:20nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Abneri sì tọ Dafidi wá ní Hebroni, ogún ọmọkùnrin sì lọ pẹ̀lú rẹ̀ Dafidi sì ṣe àsè fún Abneri àti fún àwọn ọmọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.
- 2 Samuẹli 3:21nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Abneri sì wí fún Dafidi pé, “Èmi ó dìde, èmi ó sì lọ, èmi ó sì kó gbogbo Israẹli jọ sọ́dọ̀ ọba olúwa mi, wọn ó sì bá a ṣe àdéhùn, ìwọ ó sì jẹ ọba gbogbo wọn bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́.” Dafidi sì rán Abneri lọ; òun sì lọ ní àlàáfíà.
- 2 Samuẹli 3:22nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ, òun sì ti lọ ní àlàáfíà.
- 2 Samuẹli 3:23nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà.
- 2 Samuẹli 3:24nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ.
- 2 Samuẹli 3:25nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.”
- 2 Samuẹli 3:26nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Joabu sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Abneri, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sira, Dafidi kò sì mọ̀.
- 2 Samuẹli 3:27nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀.
- 2 Samuẹli 3:28nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi sì gbọ́ ọ, ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Olúwa títí láé, ní ti ẹ̀jẹ̀ Abneri ọmọ Neri,
- 2 Samuẹli 3:29nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
jẹ́ kí ó wà ní orí Joabu, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní ààrùn ìsun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi idà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Joabu.”
- 2 Samuẹli 3:30nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
(Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.)
- 2 Samuẹli 3:31nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀.
- 2 Samuẹli 3:32nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún.
- 2 Samuẹli 3:33nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?
- 2 Samuẹli 3:34nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.
- 2 Samuẹli 3:35nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!”
- 2 Samuẹli 3:36nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn, gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà.
- 2 Samuẹli 3:37nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri.
- 2 Samuẹli 3:38nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli.
- 2 Samuẹli 3:39nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jẹ ọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Seruiah sì le jù mí lọ: Olúwa ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”
- 2 Samuẹli 4:1nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọmọ Saulu sì gbọ́ pé, Abneri kú ní Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ sì rọ, gbogbo Israẹli sì rẹ̀wẹ̀sì.
- 2 Samuẹli 4:2nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ọmọ Saulu sì ní ọkùnrin méjì tí í ṣe olórí ẹgbẹ́ ogun: a ń pe orúkọ ọ̀kan ní Baanah, àti orúkọ èkejì ní Rekabu, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti ti àwọn ọmọ Benjamini (nítorí pé a sì ka Beeroti pẹ̀lú Benjamini).