Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 65:8nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa wí: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàrà tí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘Má ṣe bà á jẹ́, nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi; Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.

  2. Isaiah 65:9nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu, àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì; àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn, ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.

  3. Isaiah 65:10nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran, àti àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran, fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.

  4. Isaiah 65:11nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,

  5. Isaiah 65:12nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà, àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa; nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn. Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀. Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.”

  6. Isaiah 65:13nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun; ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu, ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin; àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀, ṣùgbọ́n a ó dójútì yin.

  7. Isaiah 65:14nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin láti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókè láti inú ìrora ọkàn yín àti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.

  8. Isaiah 65:15nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; Olúwa Olódùmarè yóò sì pa yín, ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun yóò fún ní orúkọ mìíràn.

  9. Isaiah 65:16nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.

  10. Isaiah 65:17nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

  11. Isaiah 65:18nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.

  12. Isaiah 65:19nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.

  13. Isaiah 65:20nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀, tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán; ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé; ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kan ni a ó pè ní ẹni ìfibú.

  14. Isaiah 65:21nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọn wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn.

  15. Isaiah 65:22nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́.

  16. Isaiah 65:23nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán, wọn kí yóò bímọ fún wàhálà; nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.

  17. Isaiah 65:24nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn; nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.

  18. Isaiah 65:25nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.

  19. Isaiah 66:1nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa wí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà? Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

  20. Isaiah 66:2nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni Olúwa wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.

  21. Isaiah 66:3nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà. Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn,

  22. Isaiah 66:4nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”

  23. Isaiah 66:5nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

  24. Isaiah 66:6nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá! Ariwo tí Olúwa ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn.

  25. Isaiah 66:7nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    “Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.