Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sekariah 3:2nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”

  2. Sekariah 3:3nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà.

  3. Sekariah 3:4nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.” Ó sì wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo mú kí àìṣedéédéé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”

  4. Sekariah 3:5nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.

  5. Sekariah 3:6nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé:

  6. Sekariah 3:7nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.

  7. Sekariah 3:8nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “ ‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ẹ̀ka náà wá fun ìránṣẹ́ mi.

  8. Sekariah 3:9nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.

  9. Sekariah 3:10nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”

  10. Sekariah 4:1nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀,

  11. Sekariah 4:2nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀.

  12. Sekariah 4:3nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”

  13. Sekariah 4:4nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”

  14. Sekariah 4:5nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

  15. Sekariah 4:6nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  16. Sekariah 4:7nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”

  17. Sekariah 4:8nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:

  18. Sekariah 4:9nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

  19. Sekariah 4:10nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”

  20. Sekariah 4:11nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”

  21. Sekariah 4:12nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”

  22. Sekariah 4:13nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.”

  23. Sekariah 4:14nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”

  24. Sekariah 5:1nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò.

  25. Sekariah 5:2nǹkan bí 519 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”