- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Ọba 17:10nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”
- 1 Ọba 17:11nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”
- 1 Ọba 17:12nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà, bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”
- 1 Ọba 17:13nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.
- 1 Ọba 17:14nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”
- 1 Ọba 17:15nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́.
- 1 Ọba 17:16nǹkan bí 909 ṣáájú Kristi
Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Elijah sọ.
- 1 Ọba 17:17nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú.
- 1 Ọba 17:18nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?”
- 1 Ọba 17:19nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀.
- 1 Ọba 17:20nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?”
- 1 Ọba 17:21nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”
- 1 Ọba 17:22nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Olúwa sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí.
- 1 Ọba 17:23nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!”
- 1 Ọba 17:24nǹkan bí 908 ṣáájú Kristi
Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ẹnu rẹ.”
- 1 Ọba 18:1nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá pé, “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Ahabu, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.”
- 1 Ọba 18:2nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu. Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria,
- 1 Ọba 18:3nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Ahabu sì ti pe Obadiah, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Obadiah sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi.
- 1 Ọba 18:4nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.
- 1 Ọba 18:5nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Ahabu sì ti wí fún Obadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.”
- 1 Ọba 18:6nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrín ara wọn, Ahabu gba ọ̀nà kan lọ, Obadiah sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.
- 1 Ọba 18:7nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Bí Obadiah sì ti ń rìn lọ, Elijah sì pàdé rẹ̀. Obadiah sì mọ̀ ọ́n, ó dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni nítòótọ́, Elijah, olúwa mi?”
- 1 Ọba 18:8nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Elijah sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ ”
- 1 Ọba 18:9nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Obadiah sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Ahabu lọ́wọ́ láti pa?
- 1 Ọba 18:10nǹkan bí 906 ṣáájú Kristi
Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.