- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 30:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ yóò sì fi lélẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”
- Eksodu 30:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé,
- Eksodu 30:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.
- Eksodu 30:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.
- Eksodu 30:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa,
- Eksodu 30:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.”
- Eksodu 30:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Eksodu 30:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì,
- Eksodu 30:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lita mẹ́rin).
- Eksodu 30:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe. Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.
- Eksodu 30:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà,
- Eksodu 30:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí,
- Eksodu 30:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀.
- Eksodu 30:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.
- Eksodu 30:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà.
- Eksodu 30:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.
- Eksodu 30:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.
- Eksodu 30:33nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”
- Eksodu 30:34nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òsùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ,
- Eksodu 30:35nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́.
- Eksodu 30:36nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín.
- Eksodu 30:37nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnra yín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa.
- Eksodu 30:38nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
- Eksodu 31:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa wí fún Mose pé,
- Eksodu 31:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda,