Fò sí àkóónú

Zion

139 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Sion

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Zion

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.

  2. Orin fún ìgòkè. Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.

  3. Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

  4. Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.

  5. Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni: ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.

  6. Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé.

  7. Olúwa tí ó dá ọ̀run òun ayé, kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.

  8. Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá, tí ń gbé Jerusalẹmu. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  9. Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

  10. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá; wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

  11. Olúwa jẹ ọba títí láé; Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  12. Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu; yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

  13. Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn.

  14. Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

  15. Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí, àti bí ìlú tí a dó tì.

  16. A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà, àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.

  17. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

  18. Olúwa wí pé, “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.

  19. Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”

  20. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu.

  21. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná.

  22. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí Ejibiti ti ṣe.

  23. Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu wọn yóò kan sáárá, ní òkè ọmọbìnrin Sioni ní òkè Jerusalẹmu.

  24. Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni, nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti Israẹli láàrín yín.”

  25. Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”