Fò sí àkóónú

Gilead

80 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Gileadites

32.0400, 35.7200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gilead

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n sì wá sí Gileadi, àti sí ilé Tatimi Hodṣi; wọ́n sì wá sí Dani Jaani àti yíkákiri sí Sidoni.

  2. Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi (tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin).

  3. Geberi ọmọ Uri ní Gileadi (orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani). Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.

  4. Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”

  5. Ìlà-oòrùn ti Jordani ni gbogbo ilẹ̀ ti Gileadi (ẹ̀kún ilẹ̀ ti ará Gadi, Reubeni, àti Manase) láti Aroeri, tí ó wà létí kòtò Arnoni láti ìhà Gileadi sí Baṣani.

  6. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Peka ọmọ Remaliah, dìtẹ̀ sí i. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gileadi pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pekahiah pẹ̀lú Argobu àti Arie ní odi ààfin ọba ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni Peka pa Pekahiah, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  7. Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria.

  8. Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.

  9. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.

  10. Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.

  11. Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.

  12. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu,

  13. Ní ti àwọn ará Hebroni, Jeriah jẹ́ olóyè wọn gẹ́gẹ́ bí ìwé ìrántí ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, ní ti ìdílé wọn. Ní ọdún kẹrin ìjọba Dafidi, a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí, àwọn ọkùnrin alágbára láàrín àwọn ará Hebroni ni a rí ní Jaseri ní Gileadi.

  14. lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri;

  15. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase; Efraimu ni àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.

  16. Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi,

  17. Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.

  18. Yí ojú rẹ kúrò lára mi; nítorí ojú rẹ borí mi. Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.

  19. Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?

  20. Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.

  21. “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti. Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.

  22. Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli padà wá pápá oko tútù rẹ̀ òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani, a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè Efraimu àti ní Gileadi.

  23. Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn.

  24. Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

  25. Gileadi ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.