Skip to content

Gibeah

41 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Gibeath

31.8200, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gibeah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà sì wá sí Gibeah tí ó jẹ́ ìlú Saulu, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, gbogbo wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún.

  2. Saulu yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.

  3. Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600).

  4. Saulu sì dúró ní ìhà etí ìpínlẹ̀ Gibeah lábẹ́ igi pomegiranate èyí tí ó wà ní Migroni. Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin sì wà pẹ̀lú rẹ̀,

  5. Àwọn tí ó ń ṣọ́nà fún Saulu ní Gibeah ti Benjamini sì rí àwọn ọmọ-ogun ń túká ní gbogbo ọ̀nà.

  6. Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu.

  7. Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í.

  8. Àwọn ará Sifi sì gòkè tọ Saulu wá sí Gibeah, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ́ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Horeṣi, ní òkè Hakila, tí ó wà níhà gúúsù ti Jeṣimoni.

  9. Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?”

  10. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún Olúwa ní Gibeah ti Saulu ẹni tí Olúwa ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.”

  11. Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa, Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini;

  12. Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini, Benaiah ará Piratoni,

  13. Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.” Rama mì tìtì Gibeah ti Saulu sálọ.

  14. “Fọn fèrè ní Gibeah, kí ẹ sì fun ìpè ní Rama. Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni; máa wárìrì, ìwọ Benjamini.

  15. Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  16. “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli, ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?