Fò sí àkóónú

Assyria

115 verses · 5 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Asshur, Assur, Assyrian, Assyrians

36.3500, 43.1500 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Assyria

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

  2. Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  3. Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn.

  4. Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀,

  5. Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah, “ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé?

  6. “ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba Asiria, èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí!

  7. Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria!

  8. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba Asiria lọ́wọ́.’

  9. “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀,

  10. “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria bí?

  11. Ó lè jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀gágun ẹni tí ọ̀gá rẹ̀ ọba Asiria ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣe ẹlẹ́yà, àti pé òun ni yóò bá a wí nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún àwọn tí ó ṣẹ́kù tí wọ́n sì wà láààyè.”

  12. Isaiah sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé, ‘Ohun tí Olúwa sọ nìyìí. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba Asiria tí ó wà nínú ìdè ti fi sọ̀rọ̀-òdì sí mi.

  13. Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.

  14. “Ẹ sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ nígbà tí ó sọ pé, ‘A kì yóò jọ̀wọ́ Jerusalẹmu fún ọba Asiria.’

  15. Dájúdájú, ìwọ ti gbọ́ ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó pa wọ́n run pátápátá. Ǹjẹ́ a ó ha dá ọ nídè bí?

  16. “Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.

  17. Lẹ́yìn náà Isaiah ọmọ Amosi rán iṣẹ́ kan sí Hesekiah: “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ pé, nítorí pé ìwọ ti gbàdúrà sí mi nípa Sennakeribu ọba Asiria,

  18. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.

  19. Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.

  20. Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.

  21. Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti láti lọ mu omi ní Ṣihori? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?

  22. Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri láti yí ọ̀nà rẹ padà? Ejibiti yóò dójútì ọ́ gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria.

  23. “Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri, kìnnìún sì ti lé e lọ. Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ, àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli fa egungun rẹ̀ ya.”

  24. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí, “Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.

  25. O fi ara rẹ̀ fún gbajúmọ̀ ọkùnrin Asiria gẹ́gẹ́ bí panṣágà obìnrin, o fi òrìṣà gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́,