Fò sí àkóónú

Paul

179 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Saul, Mercurius

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Paul

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìyìnrere Ọlọ́run,

  2. Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa,

  3. Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

  4. Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí?

  5. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”

  6. Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù.

  7. Ìbá ṣe Paulu, tàbí Apollo, tàbí Kefa, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsin yìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; tiyín ni gbogbo wọn.

  8. Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

  9. Paulu aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti Timotiu arákùnrin wá, Sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọrinti pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní gbogbo Akaia:

  10. Ṣùgbọ́n èmi Paulu fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kristi bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàrín yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín.

  11. Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.

  12. Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun.

  13. Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

  14. Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.

  15. Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi, Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì:

  16. Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa,

  17. bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.

  18. Ìkíni láti ọwọ́ èmi Paulu. Ẹ máa rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.

  19. Paulu, Sila àti Timotiu, A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi: Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.

  20. Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà.

  21. Paulu, Sila àti Timotiu, Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

  22. Èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.

  23. Paulu, aposteli Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jesu Kristi ìrètí wa,

  24. Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu,

  25. Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run—