Fò sí àkóónú

Paul

179 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Saul, Mercurius

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Paul

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

  2. Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

  3. Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

  4. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”

  5. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Paulu.

  6. Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu.

  7. Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.

  8. Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”

  9. Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”

  10. Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.

  11. Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

  12. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn.

  13. Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀.

  14. Lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún Anania olórí àlùfáà náà sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn alàgbà àti ẹnìkan, Tertulu agbẹjọ́rò, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ẹjọ́ Paulu fún baálẹ̀.

  15. Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Paulu sì dáhùn wí pe, “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀tayọ̀ wí tí ẹnu mi.

  16. Ó sì pàṣẹ fún balógun ọ̀run kan kí ó máa ṣe ìtọ́jú Paulu, kí ó fún un ní ààyè, àti pé kí ó má ṣe dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un.

  17. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan Feliksi pẹ̀lú Drusilla ìyàwó rẹ̀ dé, obìnrin tí í ṣe Júù. Ó ránṣẹ́ pé Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.

  18. Ní àkókò yìí kan náà, ó ń retí pẹ̀lú pé Paulu yóò mú owó ẹ̀yìn wá fún òun, kí òun ba à lè dá a sílẹ̀, nítorí náà a sì máa ránṣẹ́ sì í nígbàkígbà, a máa bá a sọ̀rọ̀.

  19. Lẹ́yìn ọdún méjì, Porkiu Festu rọ́pò Feliksi, Feliksi sì ń fẹ́ ṣe ojúrere fún àwọn Júù, ó fi Paulu sílẹ̀ nínú túbú.

  20. ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́.

  21. Ṣùgbọ́n Festu dáhùn pé, “A pa Paulu mọ́ ní Kesarea, àti pé òun tìkára òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

  22. Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun.

  23. Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

  24. Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?”

  25. Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú.