Fò sí àkóónú

Paul

179 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Saul, Mercurius

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Paul

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú.

  2. Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè.

  3. Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.”

  4. Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde.

  5. Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.” Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé,

  6. Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

  7. Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!”

  8. Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

  9. Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

  10. Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu.

  11. Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

  12. Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn.

  13. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ.

  14. Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.

  15. Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari. Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’

  16. Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

  17. Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun.

  18. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀.

  19. Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.

  20. Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.

  21. Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.

  22. Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.

  23. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Paulu pe àwọn olórí Júù jọ. Nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti ṣe pé èmi kò ṣe ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, síbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Romu lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerusalẹmu wá.

  24. Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrín ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Paulu sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah wí pé:

  25. Paulu sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.