Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ́ tí Olúwa ti ipasẹ̀ Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani létí Jeriko.

  2. Wọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose sọ fún gbogbo Israẹli ní aginjù, aginjù ìlà-oòrùn Jordani, ni Arabah, ní òdìkejì Ṣufi, ní àárín Parani àti Tofeli, Labani, Haserotu àti Disahabu.

  3. Ní ìgbà tí ó pé ogójì ọdún, ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kọ́kànlá, Mose sọ ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ nípa àwọn ọmọ Israẹli fún wọn.

  4. Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani tí ó wà nínú ilẹ̀ Moabu ni Mose bẹ̀rẹ̀ sísọ àsọyé òfin wọ̀nyí wí pé:

  5. Mose sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀-oòrùn Jordani.

  6. Èyí ni òfin tí Mose gbé kalẹ̀ fún àwọn ará Israẹli.

  7. Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀rí, àti ìlànà àti ìdájọ́ tí Mose fi lélẹ̀ fún ún àwọn ọmọ Israẹli, lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Ejibiti.

  8. Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Beti-Peori ní ìlà-oòrùn Jordani; ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn Amori tí ó jẹ ọba Heṣboni tí Mose àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Ejibiti bọ̀.

  9. Mose sì pe gbogbo Israẹli jọ, ó sì wí pé, Gbọ́ ìwọ Israẹli, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etí ìgbọ́ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.

  10. Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́.

  11. Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.

  12. Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

  13. Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pàṣẹ fún Mose láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Moabu, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Horebu.

  14. Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé, ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí Olúwa ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.

  15. Nígbà náà ni Mose jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Israẹli pé,

  16. Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn.

  17. Nígbà náà ni Mose kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, tí ń gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli.

  18. Nígbà náà ni Mose pàṣẹ fún wọn, “Ní òpin ọdún méje méje, ní àkókò ọdún ìdásílẹ̀, nígbà àjọ àwọn àgọ́.

  19. Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́ etílé báyìí. Pe Joṣua kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Mose àti Joṣua wá, wọ́n sì fi ara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ.

  20. Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ìwọ ń lọ sinmi pẹ̀lú àwọn baba à rẹ, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣe àgbèrè ara wọn sí ọlọ́run àjèjì ilẹ̀ tí wọn ń wọ̀ lọ láìpẹ́. Wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀ wọn yóò sì da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá.

  21. Nígbà náà ni Mose kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Israẹli.

  22. Lẹ́yìn ìgbà tí Mose ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin,

  23. ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ń gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa:

  24. Mose sì ka ọ̀rọ̀ inú orin yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin sí etí ìgbọ́ ọ gbogbo ìjọ Israẹli:

  25. Mose sì wá ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí ní etí àwọn ènìyàn náà, òun, àti Hosea ọmọ Nuni.