Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Níbẹ̀, ní ojú àwọn ará Israẹli, Joṣua sì ṣe àdàkọ òfin Mose èyí tí ó ti kọ sí ara òkúta náà.

  2. Gbogbo Israẹli, àjèjì àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí Olúwa tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní òkè Gerisimu, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ebali, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  3. Kò sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mose pàṣẹ tí Joṣua kò kà ní iwájú gbogbo àjọ Israẹli, títí fi kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn àjèjì tí ń gbé ní àárín wọn.

  4. Wọ́n sì dá Joṣua lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájúṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.

  5. Joṣua sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.

  6. Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.

  7. Nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  8. Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, ó sì fi fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn. Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.

  9. Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

  10. Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.

  11. ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.

  12. Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé,

  13. gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà.

  14. Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.

  15. Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé.

  16. Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko.

  17. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Lefi, Mose kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

  18. Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mose.

  19. Mose ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi ni kò fi ìní fún ní àárín àwọn tí ó kù.

  20. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  21. Àwọn ọkùnrin Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Gilgali. Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí Olúwa sọ fún Mose ènìyàn Ọlọ́run ní Kadeṣi-Barnea nípa ìwọ àti èmi.

  22. Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa rán mi láti Kadeṣi-Barnea lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú,

  23. Ní ọjọ́ náà, Mose búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi.’

  24. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i Olúwa dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùndínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùn-ún ọdún.

  25. Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà.