Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mose sì pe Besaleli àti Oholiabu àti gbogbo ọlọ́gbọ́n ènìyàn ẹni tí Olúwa ti fún ni agbára àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ láti wá sé iṣẹ́ náà.

  2. Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀.

  3. Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi Olúwa ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.”

  4. Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i,

  5. Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà.

  6. (Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mose.

  7. Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  8. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  9. Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  10. Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  11. Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  12. Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  13. Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  15. Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

  16. Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  17. Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.

  18. Olúwa sì wí fún Mose pé,

  19. Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  20. Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

  21. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  22. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  23. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  24. Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  25. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.