Fò sí àkóónú

Moses

774 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Moses

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run.

  2. Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà.

  3. Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá.

  4. Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

  5. Olúwa sì wí fún Mose pé,

  6. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé,

  7. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé,

  8. Olúwa sọ fún Mose pé,

  9. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òsùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ,

  10. Olúwa wí fún Mose pé,

  11. Olúwa wí fún Mose pé,

  12. Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

  13. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”

  14. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.

  15. Olúwa wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn.

  16. Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára?

  17. Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.

  18. Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”

  19. Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”

  20. Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’

  21. Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.

  22. Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.

  23. Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ènìyàn.

  24. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”

  25. Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”