Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

  2. “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe àjọ ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

  3. Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó.

  4. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ.

  5. Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra.

  6. Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

  7. Olúwa sọ fún Mose pé,

  8. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.

  9. Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

  10. Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

  11. Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

  12. Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

  13. Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.

  14. Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

  15. Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé, “Dìde, Olúwa! Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

  16. Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé, “Padà, Olúwa, sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”

  17. Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etí ìgbọ́ Olúwa. Ìbínú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí. Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárín wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó.

  18. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mose, Mose sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú.

  19. Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrín wọn.

  20. Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú.

  21. Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí.

  22. Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn.

  23. Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”

  24. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú àádọ́rin ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.

  25. Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú díẹ̀ nínú agbára Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.