Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.

  2. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn.

  3. Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.

  4. Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”

  5. Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.

  6. tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.

  7. Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

  8. Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí.

  9. Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

  10. Tí í ṣe ọmọ Enosi, tí í ṣe ọmọ Seti, tí í ṣe ọmọ Adamu, tí í ṣe ọmọ Ọlọ́run.

  11. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

  12. Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”

  13. Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”

  14. Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí.

  15. Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

  16. “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

  17. “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”

  18. Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Òun ni Kristi náà.

  19. Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú, nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”

  20. Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti.

  21. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.”

  22. Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.

  23. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwa rí ohun ìyanu lónìí.”

  24. bi ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo?”

  25. Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.