God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó gbogbo idẹ náà lọ sí Babeli.
Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ.
Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.
Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì ṣí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa, nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”
Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
“Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá. Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.
“Ó rán iná láti òkè sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi. Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi, ó sì yí mi padà. Ó ti pa mí lára mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.
“Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà; ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀. Wọ́n ti yí ọrùn mi ká Olúwa sì ti dín agbára mi kù. Ó sì ti fi mí lé àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.
“Olúwa kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.
Sioni na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un Jerusalẹmu ti di ohun aláìmọ́ láàrín wọn.
“Olóòtítọ́ ni Olúwa, ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn; ẹ wò mí wò ìyà mi. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.
“Olúwa, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira! Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi, ìdààmú dé bá ọkàn mi nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi. Ní gbangba ni idà ń parun; ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.
“Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi. Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi; wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe. Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde, kí wọ́n le dàbí tèmi.
“Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ; jẹ wọ́n ní yà bí o ṣe jẹ mí ní yà nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”
Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sioni pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀! Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀, láti ọ̀run sí ayé; kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
Láìní àánú ni Olúwa gbé ibùgbé Jakọbu mì; nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀. Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.
Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo Israẹli. Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé. Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni.
Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra. Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.
Olúwa dàbí ọ̀tá; ó gbé Israẹli mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Juda.
Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú Sioni gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.
Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.
Olúwa pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya. Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀.
Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.
Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.