God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa. Odi ọmọbìnrin Sioni, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi.
Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó.
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó. Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí. Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ Olúwa?
“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ, Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.
“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi. Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè; àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀tá mi parun.”
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.